[Music] The Ogbomoso Anthem

The Ogbomoso Anthem Lyrics….

1. Ogbomoso Ajilete
Si ogo re l’a fe korin
Iwo t’a te s’arin odan
Okan ninu ilu Akin.

2. A-to-sa-si n’jo t’o buru
Abo f’eniti eru mba
Odi t’ota ko le parun,
Ogun Filani ko ri mi.

3. Oluwa olodumare
F’ow’otun re d’ilu wa mu
F’oba at’won ‘gbimo wa
L’emi at’ife ododo.

4. Kede re fun gbogbo eda
Egan ni “he” erin tobi
Ajanaku po, o ju ra
Ilu na l’ola gbangba ni.

5. N’ijo ‘re elere ni iwa
B’ise ya, a se kangun ni
Omo Shoun fe ilu won
Ilu nwon ni Orisa nwon.

6. So f’awon wundia ti ndan
Fawon Okunrin rogbodo
E ho ye, e sape, e fo
Ilu ‘bukun! L’a bi nyin si.

7. Awon Odo Ogbomoso
Yarin ‘ta re, ilu ti wa
Koto pelu gegele re
Igbo odan re l’ayo wa.

8. Ki lo le mu wa gbagbe re
Ilu ‘Telorun at’ayo
Titi a o fi s’asunji
L’a o ma korin inyin re.

Ade’nu Oko a sin mi -(a folk song.)
Ati de ‘nu oko a simi,
Ade’nu oko a simi
Ogun kan ko ja ja ja
Ko ko Ogbomoso ri
Ade’nu oko a simi.

Listen and download this…..

DOWNLOAD HEREπŸ‘ˆπŸ‘ˆ

Composed by: Late Mr. D. Oladele Ajao
Former Senior Tutor, Baptist College, Iwo
(Harmony done by Rev A. B. Adeleke)

Be the first to comment

Leave a Reply

Your email address will not be published.